Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 82 ’Gba Jehofah da aiye Lyrics

Hymn 82 ’Gba Jehofah da aiye Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 ’Gba Jehofah da aiye,
’Gbat’ o soro t’ o si se,
Awon Angeli nkorin
Halleluya gb’ orun kan.

2 Orin ’yin l’ a ko l’ oro
Gbat’ a bi Olugbala;
Orin ’yin ni a si ko
Nigbat’ o digbekun lo.

3 ’Gbat’ aiye y’o koja lo,
Iyin o gb’ ojo na kan;
’Gbat’ a o d’ aiye titun,
Orin iyin l’ a o ko.

4 Awa o ha dake bi
Titi joba na o de?
Beko ! Ijo o ma ko
Orin mimo at’ iyin.

5 Enia mimo l’ aiye,
Nf’ ayo korin iyin na;
Nipa ’gbagbo ni nwon nko,
Bi nwon o ti ko l’ oke.

6 Nigba emi o ba pin
Orin ni o segun ’ku;
Ninu ayo ailopin
Nwon o ma korin titi. Amin

Exit mobile version