Hymn 80 Wo ! gbogbo ile okunkun Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Wo ! gbogbo ile okunkun,
Wo ! okan mi, dro je;
Gbogbo ileri ni o nso
T’ ojo ayo t’o l’ogo;
Ojo ayo ! Ojo ayo !
K’ owuro re yara de !
2 Ki India on Afrika,
K’ alaigbede gbogbo ri
Isegun nla t’ o logo ni,
T’ ori oke Kalfari;
K’ ihinrere, K’ ihinrere
Tan lat’ ilu de ilu.
3 Ijoba t’ o wa l’ okunkun,
Jesu, tan ’mole fun won.
Lat’ ila- orun de ’wo re,
K’ imole le okun lo;
K’ irapada, k’ irapada,
Ti a gba l’ ofe bori.
4 Ma tan lo, ’wo ihinrere,
Ma segun lo, ma duro:
K’ ijoba re aiyeraiye
Ma bi si, k’ o si ma re;
Olugbala, Olugbala,
Wa joba gbogbo aiye. Amin.