Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 79 Ojo ayo nlanla na de Lyrics

Hymn 79 Ojo ayo nlanla na de Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Ojo ayo nlanla na de,
Eyi t’ araiye ti nreti;
Nigbat’ Olugbala w’ aiye
Nigbat’ a bi ninu ara.

2 Olusagutan ni papa
Bi nwon tin so agutan won,
Ni ihin ayo na ko ba.
Ihin bibi Olugbala.

3 Angel iranse Oluwa
L’ a ran si won, alabukun,
Pelu ogo t’ o tan julo,
Lati so ihin ayo yi.

4 Gidigidi l’ eru ba won,
Fun ajeji iran nla yi;
“Ma beru” l’ oro iyanju
T’ o t’ enu Angeli na wa.

5 A bi Olugbala loni;
Kristi Oluwa aiye ni;
N’ ilu nla Dafidi l’ o wa,
N’ ibuje eran l’ a te si.

6 “Ogo fun Olorun” l orun
Ti enia y’o ko s’ orun;
Fun ife Re laini opin,
T’ o mu Alafia w’ aiye. Amin.

Exit mobile version