Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 75 Ji, ’wo Kristian, k’ o ki oro ayo Lyrics

Hymn 75 Ji, ’wo Kristian, k’ o ki oro ayo Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Ji, ’wo Kristian, k’ o ki oro ayo
Ti a bi Olugbala araiye;
Dide, k’ o korin ife Olorun,
T’ awon Angeli nko n’ ijo kini.
Lat’ odo won n’ ihin na ti bere;
Ihin Om’ Olorun t’ a bi s’aiye.

2 ’Gbana l’ a ran akede Angeli,
T’ o so f’ awon Olusagutan, pe,
“ Mo mu ’hin rere Olugbala wa,
T’ a bi fun nyin ati gbogbo aiye.
Olorun mu ’leri Re se loni,
A bi Olugbala Krist Oluwa.”

3 Bi akede Angel na ti so tan,
Opolopo ogun orun si de;
Nwon nkorin ayo t’ eti ko gbo ri,
Orun si ho fun yin Olorun pe,
“Ogo ni f’ Olorun l’ oke orun,
Alafia at’ ife s’ enia.”

4 O ye k’ awa k’ o ma ro l’ okan wa,
Ife nla t’ Olorun ni s’ araiye;
T’ o wa jiya oro agbelebu.
Ki awa si tele liana Re,
Titi a o fi de ’bugbe l’ oke.

5 Nigbana ’gba ba de orun lohun,
A o korin ayo t’ irapada;
Y’o ma ran yi wa ka titi lailai;
A o ma korin ife Re titi,
Oba Angeli, Oba enia. Amin.

Exit mobile version