Hymn 71 Olorun ! kini mo ri yi ! Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Olorun ! kini mo ri yi !
Opin de f’ ohun gbogbo !
Onidajo araiye yo,
O gunwa n’ ite ’dajo.
Ipe dun, iboji sit u
Gbogbo awon oku sile:
Mura, lo ko, okan mi.
2 Oku ’nu Krist y’o ko jinde,
Nigba ’pe kehin ba dun;
Nwon o lo ko l’ awosanma,
Nwon o fi ayo yi ka:
Ko s’ eru ti y’o b’ okan won;
Oju Re da imole bo,
Awon ti o mura de.
3 Sugbon elese t’ on t’ eru !
Ni gbigbona ’binu Re,
Nwon o dide, nwon o si ri,
Pe, ose won ko ba mo;
Ojo ore- ofe koja;
Nwon ngbon niwaju ’te ’dajo,
Awon ti ko mura de.
4 Olorun kini mo ri yi;
Opin de f’ ohun gbogbo !
Onidajo araiye yo,
O gunwa n’ ite ’dajo.
L’ese agbelebu, mo nwo
’Gbat’ ohun gbogbo y’ o koja;
Bayi ni mo nmura de. Amin.
