Hymn 70 Wo ! Oluwa l’ awosanma Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Wo ! Oluwa l’ awosanma,
O mbo l’ ogo, l’ ola Re.
Eni t’ a pa fun elese
Mbo pelu Angeli Re;
Halleluya !
Halleluya ! Amin.
2 Gbogbo eda, wa wo Jesu,
Aso ogo l’ a wo fun;
Awon t’ o gan, awon t’ o pa,
T’ o nkan mo agbelebu;
Nwon o sokun
Bi nwon ba ri Oluwa.
3 Erekusu, okun, oke,
Orun, aiye, a fo lo
Awon t’ o ko a da won ru,
Nigbati nwon gbohun Re,
Wa s’ idajo
Wa s’ idajo, wa kalo !
4 Irapada t’ a ti nreti,
O de pelu ogo nla:
Awon ti a gan pelu Re
Yio pade Re loj’ orun !
Halleluya
Ojo Olugbala de. Amin.
