Hymn 69 Enyin t’ o ngb’ oke orun Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Enyin t’ o ngb’ oke orun,
E so ‘Ta l’ Oba Ogo’ ?
Ta l’ o ga julo nibe ?
T’ o si l’ agbara gbogbo?
2 Od’ Agutan nikan ni,
L’ o pe oye na ni t’ On;
On l’ o wa lori ite,
On si ni Oba Ogo.
3 Ihin nla ! Jesu l’ Oba,
On nikan l’ o si joba;
W’ odo Re t’ enyin t’ ore,
E’ wole niwaju Re.
4 Je k’ aiye k’ o rerin Re,
Je kin won ko lati sin,
Angle nyo l’ oruko Re,
Gbogbo eda orun nsin.
5 A yin O, ’Wo t’ Angel nsin,
Od’ Agutan Olorun,
Ma joba titi lailai
Oba ye O, Oluwa. Amin.
