Hymn 64 Iwo Onidajo Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Iwo Onidajo,
A fere duro na,
Pelu ayo tabi eru,
Niwaju ite Re:
Jo pese okan wa,
Fun ojo nlanla ni;
Fi emi irora kun wa
At’ emi adura.
2 K’ a ma wo ona Re,
L’ akoko aimo ni;
Nigbat’ Iwo o sokale,
Ninu Olanla Re.
Iwo eni aiku
Lati da wa lejo;
T’ iwo ti ogun Baba Re
At’ ore- ofe Re.
3 K’ a le ba wa bayi
Nigboran s’ oro Re;
K’ a ma teti s’ohun ipe,
K’ a ma wo ona Re.
K’ a wa ipo ayo
T’ awon olubukun,
K’ a si sora nigba die,
Fun ’simi ailopin. Amin.