Hymn 63 L’ eba odo Jordani ni Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 L’ eba odo Jordani ni,
Onibaptisi nke wipe;
Oluwa mbo ! Oluwa mbo !
E gbo ’hin ayo; Oba mbo.
2 K’ese tan ni gbogbo okan,
K’ Olorun ba le ba wa gbe;
K’ a pa ile okan wa mo
Ki Alejo nla yi to de.
3 Jesu, iwo n’ igbala wa,
Esan, ati alabo wa;
B’ itanna l’ awa ’ba segbe
Bikose t’ ore- ofe Re.
4 S’ awotan awon alaisan,
Gb’ elese t’ o subu dide;
Tan’mole Re ka ’bi gbogbo,
Mu ewa aiye bo s’ ipo.
5 K’ a f’ iyin f’ Omo Olorun,
Bibo eni ’mu dande wa;
Eni t’ a nsin pelu Baba,
At’ Olorun Emi Mimo. Amin.