Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 590 Wo oro t’o dun julo Lyrics

Hymn 590 Wo oro t’o dun julo Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 ’Wo oro t’o dun julo,
Ninu eyit’ a ri
Ileri at’ imuse
Awamaridi ni:
Nigba ekun at’ ayo,
’Yemeji at’ eru,
Mo gbo Jesu wipe, “Wa,”
Mo si lo sodo Re.
Wa, wa sodo Mi,
Wa, wa sodo Mi,
Alare t’orun nwo,
Wa ! wa sodo Mi.

2 Emi mi, ma sako lo
Kuro lod’ Ore yi!
Sunmo O, a! sunmo O,
Ba gbe titi d’opin;
A! alailera l’emi,
Ese mi papoju;
Mo nsako nigbagbogbo,
Mo si tun pada wa.
Wa! wa sodo Mi! &c.;

3 Ma fa mi sunm’ odo Re,
Ki “Wa” yi ba le je
Ohun ti a fo jeje
F’ eni t’o sunmo O;
Okun ati oke nla
Ki yio da mi duro
Lati di owo Re mu,
Nigbat’ O wipe, “Wa.”
Wa! wa sodo Mi! &c.; Amin.

Exit mobile version