Hymn 588 Gb’ adura wa, Oba aiye Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Gb’ adura wa, Oba aiye,
’Gbat’ a wole fun O;
Gbogbo wa nkigbe n’ irele,
A mbebe fun anu.
Tiwa l’ ebi, Tire l’ anu,
Mase le wa pada;
Sugbon gbo ’gbe wa n’ite Re,
Ran adura wa lowo.
2 Ese awon baba wa po,
Tiwa ko si kere;
Sugbon lati irandiran,
L’O ti f’ ore Re han.
Nigba ewu, b’omi jija,
Yi ilu wa yi ka,
Iwo l’a wo, t’a si kepe,
K’ a ma ri ranwo Re.
3 L’ ohun kan, gbogbo wa wole,
L’ abe ibawi Re;
Gbogbo wa njewo ese wa,
A ngbawe fun ’le wa.
F’ oju anu wo aini wa,
Bi a ti nkepe O;
Fi idajo Re ba wa wi,
Da wa si l’ anu Re. Amin.