Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 581 Awa fe ohun aiye yi Lyrics

Hymn 581 Awa fe ohun aiye yi Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Awa fe ohun aiye yi,
Nwon dara l’ oju wa;
A fe k’a duro pe titi,
Laifi won sile lo.

2 Nitori kini a nse be?
Aiye kan wa loke;
Nibe l’ ese on buburu
Ati ewu ko si.

3 Aiye t’o wa loke orun,
Awa iba je mo!
Ayo, ife, inu rere,
Gbogbo re wa nibe.

4 Iku, o wa ni aiye yi;
Ko si loke orun;
Enia Olorun wa mbe,
Ni aye, ni aiku.

5 K’a ba ona ti Jesu lo,
Eyi t’O la fun wa;
Sibi rere, sibi ’simi,
S’ ile Olorun wa. Amin.

Exit mobile version