Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 580 Igbala ni, igbala ni Lyrics

Hymn 580 Igbala ni, igbala ni Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Igbala ni, igbala ni
Awa elese nfe;
Nitori ninu buburu
T’a se l’ awa nsegbe.

2 Ise owo wa ti a nse,
O nwi nigbagbogbo
Pe, igbala ko si nibe,
Ise ko le gba ni.

3 Awa nsebo, awa nrubo,
A nkorin, a si njo;
Sugbon a ko ri igbala
Ninu gbogbo wonyi.

4 Nibo ni igbala gbe wa?
Fi han ni, fi han ni:
B’o wa loke, bi isale,
B’o ba mo, wi fun wa.

5 Jesu ni se Olugbala,
Jesu l’ Oluwa wa;
Igbala wa li owo Re;
Fun awa elese.

6 Wa nisisiyi, wa toro,
Ife wa ninu Re;
Enyin ti o buru l’O npe pe;
E wa gba igbala. Amin.

Exit mobile version