Hymn 58 Yo, enyin onigbagbo Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Yo, enyin onigbagbo,
Je k’ imole nyin tan:
Igba ale mbo tete,
Oru si fere de
Oko iyawo dide
O fere sunmole
Dide, gbadura, sora,
L ’oru n’ igbe y’o ta.
2 E be fitila nyin wo,
F’ ororo sinu won;
E duro de ’gbala nyin
Ipari ’se aiye:
Awon oluso nwipe,
Oko ’yawo de tan;
E pade re, b’ o ti mbo,
Pelu orin iyin.
3 Enyin wundia mimo,
Gbe ohun nyin soke
Titi, n’nu orin ayo
Pelu awon Angel.
Onje iyawo se tan,
’Lekun na si sile,
Dide arole ogo
Oko iyawo mbo
4 Enyin ti e nfi suru
Ru agbelebu nyin,
E o si joba lailai
’Gbati ’ponju ba tan.
Yi ite ogo Re ka
E o r’ Od’ agutan
E o f’ ade ogo nyin
Lele niwaju Re.
5 Jesu, ’Wo ireti wa
F’ ara Re han fun wa;
’Wo orun t’ a ti nreti
Ran s’ ori ile wa
A gbe owo wa s’oke,
Oluwa je k’ a ri
Ojo ’rapada aiye
T ’o mu wa d’ odo Re. Amin.
