Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 573 Baba wa, Olodumare Lyrics

Hymn 573 Baba wa, Olodumare Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Baba wa, Olodumare,
’Wo t’o kawo igbi omi,
’Wo t’o ti f’ ipo okun fun,
Ti ko le re ibe koja;
Gbo tiwa, gbat’ a nkepe O,
F’ awon t’o wa loju omi.

2 Olugbala, ’wo t’oro Re
Mu igbi omi pa roro,
Iwo t’o rin l’ ori omi,
T’o sun b’ enipe ko si nkan;
Gbo tiwa, gbat’ a nkepe O
F’ awon t’o wa loju omi.

3 Metalokan, Alagbara,
Dabobo won ninu ewu;
Lowo apata at’ iji,
Lowo ina ati ota;
Si je k’a ma korin ’yin Re,
L’ or’ ile ati lor’ omi. Amin.

Exit mobile version