Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 569 Ise gbogbo ti awa nse Lyrics

Hymn 569 Ise gbogbo ti awa nse Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Ise gbogbo ti awa nse,
Ni Olorun ti ri;
Ero gbogbo t’o wa ninu,
Ni Olorun si mo.

2 A ko le f’ese wa pamo,
Gbogbo won l’ O ti mo:
A npuro, a ntan ’ra wa je,
B’ a ro pe ko mo won.

3 Ohun gbogbo han ni gbangba,
Ni oju Olorun;
Okunkun ati imole,
Si ri bakanna fun.

4 Olorun, je k’a ranti pe,
Oju re si ri wa;
Si je ki awa k’o beru
Lati dese si O. Amin.

Exit mobile version