Hymn 565 Alleluya! Orin t’o dun Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Alleluya! Orin t’o dun,
Ohun ayo ti ki ku:
Alleluia! Orin didun,
T’ awon t’o wa lorun fe;
N’le ti Olorun mi ngbe,
Ni nwon nko tosantoru.
2 Alleluya! Ijo orun,
E le korin ayo na.
Alleluia! Orin ‘segun
Ye awon t’a rapada
Awa ero at’ alejo,
Iyin wa ko nilari.
3 Alleluya! Orin ayo
Ko ye wa nigbagbogbo.
Alleluia! Ohun aro
Da mo orin ayo wa;
Gbat’ a wa laiye osi yi,
A ni gbawe f’ ese wa.
4 Iyin dapo m’ adua wa;
Gbo tiwa, Metalokan!
Mu wa de ‘waju Re layo,
K’a r’ Odaguntan t’a pa:
K’a le ma ko Alleluya
Nibe lai ati lailai. Amin.