Hymn 563 Ewe ti Oba orun Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Ewe ti Oba orun,
Korin didun b’e tin lo;
Korin ’yin Olugbala,
Ologo n’nu ise Re.
2 A nlo sodo Olorun,
L’ ona t’ awon baba rin;
Nwon si nyo nisisiyi,
Ayo won l’ awa o ri.
3 Korin, agbo kekere,
E o simi n’ite Re;
Ib’ a pese ’joko nyin,
Ibe si n’ ijoba nyin.
4 Woke, omo imole,
Ilu Sion wa lokan:
Ibe n’ile wa titi,
Ibe l’a o r’ Oluwa.
5 Ma sa, e duro l’ayo,
Ni eti ile ti nyin;
Kristi Omo Baba nwi
Pe, laifoya k’a ma lo.
6 Jesu, a nlo l’ase Re;
A ko ’hun gbogbo sile;
Iwo ma j’Amona wa,
A o si ma ba O lo. Amin.