Hymn 56 Jesu t’ o ga julo l’ orun Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Jesu t’ o ga julo l’ orun,
Ipa Re l’ o d’ aiye;
’Wo f’ ogo nlanla Re sile,
Lati gba aiye la.
2 O w’aiye ninu irele
Ni ara osi wa;
Nitori k’ okan t’ o rele
Le t’ ipase Re la.
3 Wiwa Re ya angel l’enu,
Ife t’ o tobi ni;
Enia l’ anfani iye
Angeli se, ko ni.
4 Nje araiye yo; san yin de,
E ho iho ayo:
Igbala mbo fun elese;
Jesu, Olorun ni.
5 Oluwa, je ki bibo Re,
Nigba erinkeji,
Je ohun ti a nduro de,
K’ o le ba wa l’ ayo. Amin.
