Hymn 557 Emi ’ba n’ egberun ahon Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Emi ’ba n’ egberun ahon,
Fun ’yin Olugbala,
Ogo Olorun Oba mi,
Isegun ore Re.
2 Jesu t’O s’eru wa d’ayo,
T’O mu banuje tan;
Orin ni l’ eti elese,
Iye at’ ilera.
3 O segun agbara ese,
O da onde sile;
Eje Re le w’ eleri mo,
Eje Re seun fun mi.
4 O soro, oku gb’ohun Re;
O gba emi titun;
Onirobinuje y’ayo,
Otosi si gba gbo.
5 Odi, e korin iyin Re;
Aditi, gbohun Re;
Afoju, Olugbala de,
Ayaro, fo f’ayo.
6 Baba mi at’ Olorun mi,
Fun mi n’iranwo Re;
Kin le ro ka gbogbo aiye,
Ola Oruko Re. Amin.