Hymn 556 Fun anu to po b’iyanrin Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Fun anu to po b’iyanrin,
Ti mo ngba l’ ojumo;
Lati’odo Jesu Oluwa,
Kil’ emi o fi fun?
2 Kini ngo fi fun Oluwa,
Lat’inu okan mi?
Ese ti ba gbogbo re je,
Ko tile jamo nkan.
3 Eyi l’ohun t’emi o se,
F’ohun t’O se fun mi;
Em’o mu ago igbala,
Ngo kepe Olorun.
4 Eyi l’ope ti mo le da,
Emi osi, are;
Em’o ma soro ebun Re,
Ngo si ma bere si.
5 Emi ko le sin b’ o ti to,
Nko n’ise kan to pe;
Sugbon em’o sogo yi pe,
Gbese ope mi po. Amin.
