Hymn 555 N’nu gbogbo ayida aiye Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 N’nu gbogbo ayida aiye,
Ayo on wahala;
Iyin Olorun ni y’o ma
Wa l’enu mi titi.
2 Gbe Oluwa ga pelu mi,
Ba mi gb’Oko Re ga;
N’nu wahala, ’gba mo kepe,
O si yo mi kuro.
3 Ogun Olorun wa yika
Ibugbe oloto;
Eniti o ba gbekele,
Yio si ri ’gbala.
4 Sa dan ife Re wo lekan,
Gbana ’wo o mo pe,
Awon t’ o di oto Re mu
Nikan l’ eni ’bukun.
5 E beru Re, enyin mimo,
Eru miran ko si;
Sa je ki ’sin Re j’ayo nyin,
On y’o ma toju nyin. Amin.
