Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 550 E je k’a yin Olorun wa Lyrics

Hymn 550 E je k’a yin Olorun wa Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 E je k’a yin Olorun wa,
Enit’ ’O wa l’ oke orun,
T’ O fi onje fun enia,
Ti O si fi fun eranko.

2 O si te oju orun lo,
O da orun on osupa;
Ise owo Re n’ irawo,
Iye won awa ko le ka.

3 O si da ara enia,
O si fun won l’ emi pelu;
O si da ni daradara,
Bi o ti ye, bi ’ba ti wa.

4 Sugbon enia dibaje,
Nwon si bo s’ inu buburu,
Ere ese ni nwon si nje,
Ni wahala ati n’ iku.

5 Sugbon je k’a yin Olorun,
On fun wa ni Kristi Jesu;
Lati wa awon t’o ti nu,
Ninu ese ti nwon ti nrin. Amin.

Exit mobile version