Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 55 Oluwa mbo; aiye o mi Lyrics

Hymn 55 Oluwa mbo; aiye o mi Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Oluwa mbo; aiye o mi,
Oke y’o sidi n’ ipo won;
At’ irawo oju orun,
Y’o mu imole won kuro.

2 Oluwa mbo; bakanna ko
Bi o ti wa n’ irele ri;
Odo- agutan ti a pa,
Eni- iya ti o si ku.

3 Oluwa mbo; li eru nla
L’ owo ina pelu ija
L’or’ iye apa Kerubu,
Mbo, Onidajo araiye.

4 Eyi ha li eniti nrin,
Bi ero l’ opopo aiye?
Ti a se ’nunibibi si?
A ! Eniti a pa l’ eyi?

5 Ika; b’ e wo ’nu apata,
B’ e wo nu iho, lasan ni;
Sugbon igbagbo t’ o segun,
Y’o korin pe, Oluwa de. Amin.

Exit mobile version