Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 545 Wa, Jesu fi ara han Lyrics

Hymn 545 Wa, Jesu fi ara han Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Wa, Jesu fi ara han,
Wa, je k’ okan wa mo O:
Wa, mu gbogb’ okan gbona
Wa, bukun wa k’a to lo.

2 Wa, f’aiya wa n’ isimi,
Wa, k’a d’ alabukunfun;
Wa, soro alafia,
Wa, busi igbagbo wa.

3 Wa, le ’siyemeji lo,
Wa, ko wa b’a ti bebe;
Wa, fun okan wa n’ ife,
Wa, fa okan wa soke.

4 Wa, so f’ okan wa k’o yo,
Wa, wipe, “ ’Wo ni mo ya;”
Wa, p’ awon agbo Re mo,
Wa, sure f’ agutan Re. Amin.

Exit mobile version