Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 534 Wakati adura didun Lyrics

Hymn 534 Wakati adura didun Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Wakati adura didun!
T’o gbe mi lo kuro laiye,
L’o ’waju ite Baba mi,
Ki nso gbogbo edun mi fun;
Nigba ’banuje at’ aro,
Adua l’ abo fun okan mi:
Emi sib o lowo Esu,
’Gbati mo ba gb’ adua didun.
Emi sib o lowo Esu,
’Gbati mo ba gb’ adua didun.

2 Wakati adura didun!
Iye re y’o gbe ebe mi
Lo sod’ Enit’ o seleri
Lati bukun okan adua:
B’ O ti ko mi, ki nw’oju Re,
Ki ngbekele, ki nsi gba gbo:
Ngo ko gbogb’ aniyan mi le,
Ni akoko adua didun.
Ngo ko gbogb’ aniyan mi le,
Ni akoko adua didun.

3 Wakati adura didun!
Je kin ma r’itunu re gba,
Titi ngo fi d’oke Pisga,
Ti ngo r’ile mi l’okere.
Ngo bo ago ara sile,
Ngo gba ere ainipekun:
Ngo korin bi mo ti nfo lo,
Odigbose! adua didun.
Ngo korin bi mo ti nfo lo,
Odigbose! adua didun. Amin.

Exit mobile version