Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 529 Jesu Oluwa ni ’se Lyrics

Hymn 529 Jesu Oluwa ni ’se Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Jesu Oluwa ni ’se
Ipile Ijo Re;
Omi ati oro Re,
Ni On si fit un da;
O t’ orun wa, O fi se
Iyawo mimo Re;
Eje Re l’O si fir a,
Ti O si ku fun u.

2 N’ ile gbogbo l’a sa won,
Sugbon nwon je okan;
Oluwa kan, ’gbagbo kan,
Ati baptisi kan;
Oruko kan ni nwon nyin,
Onje kan ni nwon nje;
Opin kan ni nwon nlepa,
Nipa ore- ofe.

3 Bi aiye tile nkegan,
gbat’ iyonu de ba;
B’ija on eko- ke- ko
Ba mu iyapa wa;
Awon mimo y’o ma ke
Wipe, “Y’ o tip e to?”
Oru ekun fere di
Oro orin ayo.

4 L’ arin gbogbo ’banuje,
At’ iyonu aiye,
O nreti ojo ’kehin
Alafia lailai;
Titi y’o f’ oju re ri,
Iran ologo na,
Ti ijo nla asegun,
Y’o d’ ijo ti nsimi.

5 L’aiye, yi o ni ’dapo
Pelu Metalokan!
O si ni ’dapo didun
Pel’ awon t’o ti sun;
A! alabukun mimo!
Oluwa, fi fun wa,
K’ a ba le ri bi awon,
K’ a ba O gbe l’orun. Amin.

Exit mobile version