Hymn 524 Ibukun ni f’oku Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Ibukun ni f’oku,
T’o simi le Jesu;
Awon t’o gb’ ori won
Le okan aiya Re.
2 Iran ’bukun l’eyi,
Ko si ’boju larin;
Nwon ri En’ Imole,
Ti nwon ti fe lairi.
3 Nwon bo lowo aiye,
Pelu aniyan re;
Nwon bo lowo ewu,
T’o nrin l’ osan, l’oru.
4 Lori iboji won,
L’awa nsokun loni,
Nwon j’ en’ ire fun wa,
T’ a ki y’o gbagbe lai.
5 A k’yo gbohun won mo,
Ohun ife didun;
Lat’ oni lo, aiye
Ki o tun mo won mo.
6 Enyin oninure,
E fi wa sile lo;
Ao sokun nyin titi,
Jesu pa sokun ri.
7 Sugbon a fe gbohun
Olodumare na;
Y’o ko, y’o si wipe,
E dide, e si yo. Amin.
