Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 523 Awa ti gbe o sin Lyrics

Hymn 523 Awa ti gbe o sin Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Awa ti gbe o sin, niwon l’ao daro re,
B’o tile je nin’ okunkun l’a sin o si;
Jesu re ti la ona kanna koja,
Fitila ife Re ni y’o ma saju re.

2 Awa ti gbe o sin, oju wa ko ri o mo,
O ko si tun ba war in laiye yi mo;
Sugbon Jesu ti n’ apa ife Re si o,
Nj’ elese le ku, nitori Jesu ti ku.

3 Awa ti gbe o sin, o ti bo ago re sile,
Boya es’ emi re kole lati lo;
Sugbon iwo ti ji s’ imole Paradise,
’Wo si ti ngbo orin awon Serafu.

4 Awa ti gbe o sin, niwon l’a o daro re,
Olorun re li Olurapada re,
O gba o lowo wa, y’o si ji o dide,
Iku ko n’ oro mo, ’tori Jesu ti ku. Amin.

Exit mobile version