Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 520 Awon mimo, lala pari Lyrics

Hymn 520 Awon mimo, lala pari Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Awon mimo, lala pari,
Nwon ti ja, nwon si ti segun,
Nwon ko fe ohun ija mo,
Nwon da won ’le l’ ese Jesu:
A! enyin eni ibukun,
Isimi nyin ti daju to!

2 Awon mimo, irin pari,
Nwon ko tun sure ije mo,
Are at’ isubu d’ opin,
Ota on eru ko si mo:
A! enyin eni ibukun,
Isimi yin ha ti dun to!

3 Awon mimo, ajo pari,
Nwon ti gun s’ ile ibukun,
Iji ko deruba won mo,
Igbi omi ko n’ ipa mo;
A! enyin eni ibukun,
E nsimi n’ ib’ alafia.

4 Awon mimo, oku won sun
Ninu ile, awon nsona
Titi nwon yio fi jinde,
Lati fi ayo goke lo:
A! eni ’bukun, e korin;
Oluwa at’ Oba nyin mbo.

5 Olorun won, ’Wo l’a nkepe,
Jesu, bebe fun wa l’ oke;
Emi Mimo, Oluto wa,
F’ ore- ofe fun wa d’ opin;
K’a le b’ awon mimo simi,
Ni Paradise pelu Re. Amin.

Exit mobile version