Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 52 Ijo ti nduro pe Lyrics

Hymn 52 Ijo ti nduro pe Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Ijo ti nduro pe
Lati ri Oluwa:
O si wa bakanna sibe
Ko s’alabaro fun !
Odun nyi lu odun,
Ojo ngori ojo,
Sibe lairi Oluwa re,
O wa ninu ofo:
Ma bo, Jesu, ma bo !

2 Awon mimo laiye
Opo won l’o ti ku
Bi nwon si tin lo l’okokan,
L’a nte won gbe ’ra won :
A te won lati sun
Ki se l’ainireti;
A te won lati reju ni
K’ile ogo to mo.
Ma bo, Jesu, Ma bo !

3 Awon ota npo si;
Agbara Esu nga;
Ogun ngbona, igbagbo nku,
Ife si di tutu.
Y’o tip e to ! Baba
Oloto, Olore !
’Wo ki y’o koya omije
At’ eje Ijo Re?
Ma bo, Jesu, ma bo.

4 A nfe gbo ohun Re,
A nfe f’oju kan O;
K’a le gba ade at’ogo
B’ a ti ngba ore Re.
Jo, wa m’ese kuro
At’ egun at’ eri,
K’o si so aiye osi yi
D’ aiye rere Tire
Ma bo, Jesu, ma bo. Amin.

Exit mobile version