Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 504 Jesu f’ ara han nitoto Lyrics

Hymn 504 Jesu f’ ara han nitoto Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Jesu f’ ara han nitoto,
Nibi ase ’yawo;
Oluwa, awa be O, wa,
F’ ara Re han nihin.

2 Fi ibukun Re fun awon
Ti o dawopo yi;
F’ ojurere wo ’dapo won,
Si bukun egbe won.

3 F’ ebun ife kun aiya won,
Fun won n’ itelorun;
Fi alafia Re kun won,
Si busi ini won.

4 F’ ife mimo so won d’ okan,
Kin won f’ ife Kristi
Mu aniyan ile fere,
Nipa ajumose.

5 Je kin won ran ’ra won lowo,
Ninu igbgbo won;
Kin won si ni omo rere,
Ti y’o gbe ’le won ro! Amin.

Exit mobile version