Hymn 500 Ojo nla l’ ojo ti mo yan Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Ojo nla l’ ojo ti mo yan
Olugbala l’ Olorun mi:
O ye ki okan mi ma yo,
K’o sir o ihin na ka ‘le.
Ojo nla l’ ojo na!
Ti Jesu we ese mi nu;
O ko mi ki mma gbadura,
Kim ma sora, ki nsi ma yo.
Ojo nla l’ ojo na!
Ti Jesu we ese mi nu.
2 Ise Igbala pari na,
Mo di t’ Oluwa mi loni;
On l’o pe mi ti mo si je,
Mo f’ ayo jipe mimo na.
Ojo nla, &c.;
3 Eje mimo yi ni mo je
F’ Eniti’ o ye lati feran;
Je k’orin didun kun ‘le Re,
Nigba mo ba nlo sin nibe.
Ojo nla, &c.;
4 Simi, aiduro okan mi,
Simi le Jesu Oluwa;
Tani je wipe aiye dun
Ju odo awon Angeli?
Ojo nla, &c;
5 Enyin orun, gbo eje mi;
Eje mi ni ojojumo
Em’ o ma so dotun titi
Iku y’o fi mu mi re ‘le.
Ojo nla, &c.; Amin.