Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 498 Mo ti seleri, Jesu Lyrics

Hymn 498 Mo ti seleri, Jesu Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Mo ti seleri, Jesu,
Lati sin O dopin;
Ma wa lodo mi titi,
Baba mi, Ore mi.
Emi k’ yo beru ogun,
B’ iwo ba sunmo mi,
Emi ki y’o si sina,
B’ o ba f’ona han mi.

2 Je ki mmo p’ o sunmo mi,
‘Tor’ ibaje aiye;
Aiye fe gba okan mi,
Aiye fe tan mi je;
Ota yi mi ka kiri,
Lode ati ninu’
Sugbon Jesu, sunmo mi,
Dabobo okan mi.

3 Je ki emi k’ o ma gbo
Oun Re, Jesu mi,
Ninu igbi aiye yi,
Titi nigbagbogbo;
So, mu k’ o da mi l’oju,
K’ okan mi ni ‘janu;
So, si mu mi gbo Tire,
‘Wo olutoju mi.

4 ‘Wo ti se ‘leri, Jesu,
F’ awon t’ o tele O,
Pe ibikibi t’ O wa,
L’ awon yio si wa;
Mo ti se ‘leri, Jesu,
Lati sin O dopin.
Je kin ma to O lehin,
Baba mi, Ore mi.

5 Je kin ma ri ‘pase Re,
Ki nle ma tele O:
Agbara Re nikan ni,
Ti mba le tele O.
To mi, pe mi, si fa mi,
Di mi mu de opin;
Si gba mi si odo Re,
Baba mi, Ore mi. Amin.

Exit mobile version