Hymn 488 Ose, Ose rere Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Ose, Ose rere,
Iwo ojo simi;
O ye k’ a fi ojo kan,
Fun Olorun rere;
B’ ojo mi ba m’ ekun wa,
Iwo n’ oju wa nu;
Iwo ti s’ ojo ayo,
Emi fe dide re.
2 Ose, Ose rere,
A kio sise loni;
A o f’ ise wa gbogbo
Fun aisimi ola.
Didan l’ oju re ma dan,
‘Wo arewa ojo;
Ojo mi nso ti lala,
Iwo nso ti ‘simi.
3 Ose, Ose rere,
Ago tile nwipe,
F’ Eleda re l’ ojo kan,
T’ O fun o n’ ijo mefa:
A o fi ‘se wa sile,
Lati lo sin nibe,
Awa ati ore wa,
Ao lo sile adua.
4 Ose, Ose rere,
Wahati re wu mi;
Ojo orun ni ‘wo se,
‘Wo apere orun:
Oluwa, je ki njogun
‘simi lehin iku;
Ki nle ma sin O titi,
Pelu enia Re. Amin.