Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 482 Omode, e sunm’ Olorun Lyrics

Hymn 482 Omode, e sunm’ Olorun Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Omode, e sunm’ Olorun,
Pelu irele at’ eru;
Ki ekun gbogbo wole fun
Olugbala at’ Ore wa.

2 Oluwa, je k’ anu Re nla,
Mu wa kun fun ope si O;
Ati b’ a ti nrin lo l’ aiye,
K’ a ma ri opo anu gba.

3 Oluwa! m’ ero buburu,
Jinna rere si okan wa;
L’ ojojumo fun wa l’ ogbon,
Lati yan ona toro ni.

4 Igba aisan, at’ ilera
Igba aini tabi oro;
Ati l’ akoko iku wa,
Fi agbara Tire gba wa. Amin.

Exit mobile version