Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 481 Gba Jesu f’ ite Re sile Lyrics

Hymn 481 Gba Jesu f’ ite Re sile Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 ’Gba Jesu f’ ite Re sile,
O mu ’po irele;
Ni ’rele o mu awo wa,
O wa gbe ’nu aiye.

2 A ba le rin bi On ti rin,
Nipa ona ogbon;
K’ a dagba l’ ore at’ ogbon,
Bi odun ti npo si.

3 Didun l’ oro, at’ iwo Re;
Gb’ awon iya sunmo;
O gbe omo won s’ apa Re,
O si sure fun wom.

4 Labe itoju Re, nwon bo
Lowo ’tanje aiye:
Bayi ni k’ awa dubule,
Ni iso oju Re.

5 ’Gba Jesu gun ketekete,
Awon ’mode nkorin;
L’ ayo nwon ke eka igi,
Nwon si te ’so sile.

6 B’ awa gbagbe iyin Jesu,
Okuta y’o korin!
Hosanna ni awa o ko,
Hosanna s’ Oba wa. Amin.

Exit mobile version