Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 480 Jesu t’ o wa l’ oke orun Lyrics

Hymn 480 Jesu t’ o wa l’ oke orun Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Jesu t’ o wa l’ oke orun,
Sokale d’ enia, o ku;
Ninu Bibeli l’ a le ri,
Bi On iti ma se rere.

2 O nkiri, o sin se rere,
O nla ’ju awon afoju;
Opo awon t’ o si yaro,
O sanu won, o si wo won.

3 Ju wonni lo, o wi fun won,
Ohun wonni t’ Olorun fe;
O si se enit’ o tutu,
Yio si gbo t’ awon ewe.

4 Sugbon iku t’ o ku buru,
A fi ko ’ri agbelebu;
Owo rere t’ o se nkan yi,
Nwon kan mo ’gi agbelebu.

5 O mo b’ enia ti buru,
O mo b’ iya ese ti ri;
Ninu anu Jesu wipe,
On o gba iya ese je.

6 Be l’ o ku nitori yin a,
O d’ enia, k’o ba le ku;
Bibeli ni, o t’ orun wa,
K’ o le dari ese ji ni.

7 Olorun o si f’ese ji
Awon t’o ronupiwada;
Je k’a ji kutu w’oju Re,
K’a si gba ekun ore Re. Amin.

Exit mobile version