Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 48 Gbo ’gbe ayo ! Oluwa de Lyrics

Hymn 48 Gbo ’gbe ayo ! Oluwa de Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Gbo ’gbe ayo ! Oluwa de,
Jesu t’a seleri;
Ki gbogbo okan mura de,
K’ ohun mura korin.

2 O de lati t’ onde sile
L’ oko eru Esu;
’Lekun ’de fo niwaju Re.
Sekeseke ’rin da.

3 O de larin ’baje aiye
Lati tan ’mole Re,
Lati mu k’awon afoju
Le f’oju won reran.

4 Ode, ’tunu f’okan ’rora,
Iwosan f’agbogbe;
Pelu ’sura or’ ofe Re
Fun awon talaka.

5 Hosanna, Oba ’Lafia,
Ao kede bibo Re;
Gbogbo orun y’o ma korin
Oruko t’a feran. Amin.

Exit mobile version