Hymn 479 Yika or’ ite Olorun Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Yika or’ ite Olorun,
Egberun ewe wa;
Ewe t’ a dari ese ji,
Awon egbe mimo:
Nkorin Ogo, ogo, ogo.
2 Wo! olukuluku won wo
Aso ala mimo;
Ninu imole ailopin,
At’ ayo ti ki sa,
Nkorin Ogo, ogo, ogo.
3 Kil’ o mu won de aiye na,
Orun t’ o se mimo,
Nib’ alafia at’ ayo,
Bi nwon ti se de ’be?
Nkorin Ogo, ogo, ogo.
4 Nitori Jesu ta ’je Re,
Lati k’ ese won lo;
A ri won ninu eje na,
Nwon di mimo laulau;
Nkorin Ogo, ogo, ogo.
5 L’ aiye nwon wa Olugbala,
Nwon fe oruko Re;
Nisisiyi nwon r’ oju Re,
Nwon wa niwaju Re;
Nkorin Ogo, ogo, ogo.
6 Orisun na ha nsan loni?
Jesu, mu wa de ’be;
K’a le ri awon mimo na,
K’a sib a won yin O,
Nkorin Ogo, ogo, ogo. Amin.