Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 478 Ona kan l’o ntoka sorun Lyrics

Hymn 478 Ona kan l’o ntoka sorun Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Ona kan l’o ntoka sorun,
Isina ni ’yoku;
Hiha si l’ oju ona na,
Awon Kristian l’o fe.

2 Lat’ aiye, o lo tarata,
O si la ewu lo;
Awon ti nf’ igboya rin I,
Y’o d’ orun nikehin.

3 Awon ewe y’o ha ti se
Le la ewu yi ja?
’Tori idekun po lona
F’ awon odomode!

4 Gbigboro lona t’ opo nrin,
O si teju pelu!
Mo si mo pe lati dese
Ni nwon se nrin nibe.

5 Sugbon k’ ese mi ma ba ye,
Ki nma si sako lo,
Oluwa, jo s’ oluto mi,
Emi ki o sina.

6 Nje mo le lo l’ ais’ ifoya,
Ki ngbekel’ oro Re;
Apa Re y’o s’ agutan Re,
Y’o si ko won de ’le.

7 Benin go la ewu yi ja
Nipa itoju Re;
Ngo tejumo ’bode orun
Titi ngo fi wole. Amin.

Exit mobile version