Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 473 Mo fe gbo itan kanna Lyrics

Hymn 473 Mo fe gbo itan kanna Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Mo fe gbo itan kanna
T’ awon angeli nso;
Bi Oba Ogo ti wa
Gbe aiye osi yi;
Bi mo tile J’elese,
Mo mo eyi daju,
Pe Oluwa wa gba mi,
’Tori O fe mi be.

2 Mo yo pe Olugbala
Ti je omode ri;
Lati fi ona mimo
Han awon omo Re;
Bi emi ba si tele
Ipase Re nihin,
On ko ni gbagbe mi lai,
’Tori O fe mi be.

3 Ife ati anu Re,
Y’o je orin fun mi;
B’emi ko tile le ri,
Mo mo pe, O ngbo mi;
O si ti se ileri,
Pe, mo le lo korin
Larin awon angeli,
’Tori O fe mi be. Amin.

Exit mobile version