Hymn 464 Mo fe ki ndabi Jesu Lyrics
Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook
1 Mo fe ki ndabi Jesu,
Ninu iwa pele;
Ko s’ enit’ o gboro ’binu
Lenu Re lekan ri.
2 Mo fe ki ndabi Jesu,
L’ adura ’gbagbogbo;
Lori oke ni On nikan
Lo pade Baba Re.
3 Mo fe ki ndabi Jesu,
Emi ko ri ka pe
Bi nwon ti korira Re to,
O s’ enikan n’ ibi.
4 Mo fe ki ndabi Jesu,
Ninu ise rere;
K’a le wi nipa temi pe,
“O se ’won t’o le se.”
5 Mo fe ki ndabi Jesu,
T’o f’iyonu wipe,
“Je k’omode wa sodo Mi,”
Mo fe je ipe Re.
6 Sugbon nko dabi Jesu,
O si han gbangba be;
Jesu fun mi l’ore- ofe
Se mi ki ndabi Re. Amin.
