Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 461 Opo ikan omi Lyrics

Hymn 461 Opo ikan omi Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Opo ikan omi,
Yanrin kekeke;
Wonyi l’ o d’ okun nla,
At’ ile aiye.

2 Iseju wa kokan,
Ti a ko kasi,
L’ o nd’ odun aimoye
Ti ainipekun.

3 Iwa ore die,
Oro ’fe die,
L’ o ns’ aiye di Eden,
Bi oke orun.

4 Isise kekeke
L’ o nmokan sina,
Kuro l’ ona rere,
Si ipa ese.

5 Ise anu die
T’a se l’omode,
Di ’bukun f’orile
T’o jina rere.

6 Awon ewe l’ ogo
Ngberin Angeli;
Se wa ye Oluwa
F’ egbe mimo won. Amin.

Exit mobile version