Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 46 Olorun ’fe, Isun anu Lyrics

Hymn 46 Olorun ’fe, Isun anu Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Olorun ’fe, Isun anu,
Ore Re tip o to !
Orisi akoko t’ o nde
L’ o nkede ajo Re.

2 Nigbat’ agbe gbin ogbin re,
T’o ri mo ’nu ile,
Iwo m’ akoko ti o nhu,
O si ran ojo wa.

3 Tire l’ agbara t’ ojo ni,
T’o nmu ’rugbin dagba;
’Wo l’o nran ’mole orun wa,
Ati iri pelu.

4 Akoko ’rugbin on ’kore,
Iwo l’o fi fun wa;
Ma je k’ a gbagbe lati mo
Ibi ’bukun ti nwa.

5 Isun ife, ’Wo n’ iyin wa;
Iwo l’a nkorin si,
Gbogbo eda l’ o si dalu
N’nu iyin didun na. Amin.

Exit mobile version