Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 459 Ojo oni lo tan Lyrics

Hymn 459 Ojo oni lo tan Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Ojo oni lo tan,
Oru sunmole:
Okunkun ti de na,
Ile si ti su.

2 Okunkun bo ile,
Awon ’rawo yo;
Eranko at’ eiye,
Lo si busun won.

3 Jesu f’ orun didun
F’ eni alare;
Je ki ibukun Re
Pa oju mi de.

4 Je k’ omo kekere
La ala rere;
S’ oloko t’ ewu nwu
Ni oju omi.

5 Ma toju alaisan
Ti ko r’ orun sun;
Awon ti nro ibi,
Jo da won l’ekun.

6 Ninu gbogbo oru,
Je k’ angeli Re
Ma se oluso mi,
L’ ori eni mi.

7 ’Gbat’ ile ba si mo,
Je k’ emi dide;
B’ omo ti ko l’ ese
Ni iwaju Re.

8 Ogo ni fun Baba,
Ati fun Omo,
Ati f’ Emi Mimo,
Lai ati lailai. Amin.

Exit mobile version