Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 451 Wo b’ Olusagutan Israel Lyrics

Hymn 451 Wo b’ Olusagutan Israel Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Wo b’ Olusagutan Israel
Ti fi ayo duro;
Lati gb’ awon Od’ agutan,
K’o si ko won mora.

2 On si wi pe, “Je ki nwon wa,”
“E mase kegan won;”
Lati sure fun iru won,
L’Oba Angel se wa.

3 Pelu ope l’ a gbe won wa,
A jowo won fun O;
A yo: bi a ti je Tire,
K’ omo wa je Tire.

4 E ma yo: odo agutan,
K’e ma saferi Re;
Pelu ayo ni k’ e sunmo,
K’o le sure fun nyin.

5 Bi a ba fi won s’aiye lo,
’Wo to Baba fun won;
Bi nwon si ku ni owo wa,
Tu wa ninu, Jesu. Amin.

Exit mobile version