Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 449 Balogun! Olugbala wa Lyrics

Hymn 449 Balogun! Olugbala wa Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Balogun! Olugbala wa,
Gb’ omo wonyi t’a bun O;
Se won ye fun ise Tire,
Arole iye wonyi.

2 Arewa Baba wa orun,
Mu k’ awon wonyi jo O
N’nu aworan Tire papa,
Lo won s’ agbala oke.

3 Se won l’ agannigan mimo,
Omo- ogun t’o lera;
Ki nwon fo itegun Esu,
Ki nwon si segun aiye.

4 K’ oro Re dabi oguna,
L’ enu awon omo Re;
Ti y’o jo ese l’ ajorun,
K’ ara ba le da sasa.

5 Pa won mo fun ’se ogo Re,
Ki nwon wa lailabawon;
Ko won lati r’ agbelebu,
Lojojumo aiye won.

6 Bukun ’lana igbala yi,
Fun ire omo wonyi;
Gba won, to won, si ma so won,
Nikehin gb’ okan won la. Amin.

Exit mobile version