Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 447 Duro, omo ogun Lyrics

Hymn 447 Duro, omo ogun Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Duro, omo ogun,
F’ enu re so f’ aiye;
Si jeje pe ofo l’ aiye,
Nitori Jesu re.

2 Dide k’ a baptis’ re,
K’ o we ese re nu,
Wa b’ Olorun da majemu,
So ’gbagbo re loni.

3 Tire ni Oluwa,
At’ ijoba orun;
Sa gb’ ami yi siwaju re,
Ami Oluwa re.

4 ’Wo k’ ise t’ ara re,
Bikose ti Kristi;
A ko oruko re po mo
Awon mimo gbani.

5 Ni hamora Jesu,
Kojuja si Esu;
B’ o ti wu k’ ogun na le to,
Iwo ni o segun.

6 Ade didara ni,
Orin na, didun ni,
Orin na, didun ni,
’Gba t’ a ba ko ikogun jo
S’ ese Olugbala. Amin.

Exit mobile version