Site icon Treasure Hymns – Yoruba

Hymn 446 Eyi l’ ase nla Jehofa Lyrics

Hymn 446 Eyi l’ ase nla Jehofa Lyrics

Youruba Iwe Orin Mimo Anglican Hymnbook

 

1 Eyi l’ ase nla Jehofa,
Yio wa titi lai;
Elese b’ iwo at’ emi,
K’ a tun gbogbo wa bi.

2 Okunkun y’o je ipa wa,
B’ a wa ninu ese;
A ki o ri ijoba Re,
Bi a ko d’ atunbi.

3 Bi baptisi wa je ’gbarun,
Asan ni gbogbo re;
Eyi ko le w’ ese wa nu,
Bi a ko tun wa bi.

4 Wo ise were ti a nse,
Ko ni iranwo Re;
Nwon ko s’ okan wa di otun,/ B’ awa ko d’ atunbi.

5 Lo kuro ninu ese re
Ja ewon Esu nu;
Gba Kristi gbo tokantokan
Iwo o d’ atunbi. Amin.

Exit mobile version